HYMN 865

1. OLUWA awa de

   Kerubu, Serafu 

   Lati je ise to ra wa 

   Fun gbogbo agbaiye.


2. lse t’o ran l’eyi

   Olorun Oluwa

   P’a won ti nb’ojo isimi je 

   Ni yio jebi poju.


3. K’araiye teriba 

   Niwaju ase Re 

   K’ibinu Olodumare 

   Le ka kuro l’aiye.


4. Kerubu Serafu 

   Enyin n’iyo aiye 

   Iluu t’a te sori oke 

   Yio ti se farasin.


5. E fun ‘pe na kikan 

   Nipa t’ojo isimi

   Ki gbogbo orile-ede 

   Le p’ojo Mimo mo.


6. E f'Ogo fun Baba

   E f'Ogo fun Omo

   E f'Ogo fun Emi Mimo 

   Metalokan lailai. Amin

English »

Update Hymn