HYMN 87

(FE 104)
“E ma yin Oluwa” Ps. 112:1
Tune: Ma toju mi Jehovah nla.1. OPE lo ye f’Olugbala

   Iyin fun Metalokan

   T’O da wa si d’ojo oni,

   A f'ogo f‘oruko Re.

Egbe: Korin Ogo, Alleluya,

      Orin ogo lao ko

      Korin Ogo, Alleluyah,

      Ko Hosannah s'Oba wa.


2. Metalokan Oba Ogo

   Baba fun wa l’agbara

   F’awon asaju n’isegun

   Fun won l’ogbon at’oye

Egbe: Korin Ogo...


3. Obangiji Oba Ogo,

   Ranti Egbe Aladura,

   Fun won l‘agbara at'ife

   Ko won l'adura t'orun.

Egbe: Korin Ogo... 


4. Jehovah-Nissi Oba wa,

   Sanu f’Egbe Serafu;

   F’isegun f’Egbe Kerubu

   Se wa gege bi t’orun.

Egbe: Korin Ogo... 


5. Awon ti ko ri ‘se yio ri,

   Agan a f’owo s’osun

   Olomo ko ni padanu,

   Alaisan yio dide.

Egbe: Korin Ogo... 


6. Gbo tiwa Baba wa orun

   Ranti Egbe idale,

   Fun won l’agbara at’ipa

   Fun gbogbo wa n'isegun

Egbe: Korin Ogo... 


7. Jehovah Shammah Oba wa,

   Gbat’ o ba d‘ojo ikehin

   Mu wa d’agbala itura,

   JAH mu wa de ‘te Ogo.

Egbe: Korin Ogo...  Amin

English »

Update Hymn