HYMN 91

(FE 108)
Tune: Elese wa sodo Jesu
"Fi ilu ati Ijo yin" - Ps. 150:41. E DAMURE enyin Seraf'

   E mu harpu nyin pelu

   E je ki Kimbali nyin dun

   Lati pade Oba wa.

Egbe: Loke odo ona Eden,

      Ibugbe mimo to dara

      Nibi Kerubu Serafu,

      Nyin Baba Mimo Logo.


2. Fi ‘lu ati ‘jo yin Baba

   Baba y'o f’ayo fun wa

   Bi awa ba je le gbagbo

   Ere pupo ni fun wa.

Egbe: Loke odo ona Eden...


3. Baba masai fi 're fun wa

   Awa Seraf' aiye yi;

   Se wa ye fun isin gbogbo

   Ka gb'ade wa nikehin.

Egbe: Loke odo ona Eden...


4. Baba to gbo ti Elijah,

   Masai gbo ti Serafu;

   Jehovah-Jire Oba wa,

   Se wa ye lojo ‘kehin.

Egbe: Loke odo ona Eden...


5. Ao f'ogo fun Baba wa,

   Fun Omo, to da wa si;

   Bi odun si ti nyipo lo,

   Metalokan la O yin.

Egbe: Loke odo ona Eden... Amin

English »

Update Hymn