HYMN 92

C.M.S. 568, 8.7.8.7.4.7 (FE 109)
“Fi ibukun fun Oluwa, iwo okan mi"
- Ps.104:11. OKAN mi yin Oba orun

   Mu ore wa sodo Re,

   ‘Wo ta wosan, ta dariji

   Tal‘a ba ha yin bi Re?

Egbe: Yin Oluwa, Yin Oluwa
      
      Yin Oba Ainipekun

      Yin Oluwa, Yin Oluwa
      
      Yin Oba Ainipekun


2. Yin fun Oko ‘gbala kehin

   To sokale f'araiye

   O si yan Bab'Aladura

   Lati je Alakoso.

Egbe: Yin Oluwa...


3. Yin fun anu to ti fihan

   Lori Egbe Serafu;

   To pa wa mo titi d'oni

   To si fun wa n'isegun.

Egbe: Yin Oluwa...


4. Yin fun abo ti o daju

   To nfun wa lojurere,

   Ninu wahala on ‘danwo

   Anu Re wa bakanna.

Egbe: Yin Oluwa...


5. Yin fun abo ti o daju

   Ta nri l'Egbe Serafu

   Aje, Oso, on Sonponnna

   Won ko ri wa gbese mo

Egbe: Yin Oluwa...


6. Bi baba ni o ntoju wa

   O si mo ailera wa,

   Jeje lo ngbe wa I'apa Re,

   O nf‘ onje iye bo wa.

Egbe: Yin Oluwa...


7. Ogun orun, e ba wa yin

   Baba, Omo, on Emi

   Orun, Osupa, e wole

   Ati gbogbo agbaiye.

Egbe: Yin Oluwa... Amin

English »

Update Hymn