HYMN 94

(FE 111)
"Gbe a gbo" - Job 5:271. JESU mo wa sodo Re,

   Je ki nle ma to O lehin

   Bi ‘ni mi gbogbo po si

   Ti ero mi gbogbo soji.

Egbe: E yin logo, enyin Mimo

      E f’ope fun Baba loke

      Da wa si I'egbe Serafu,

      Ni kehin gba okan wa la.


2. Keferi, lmale, e wa

   Onigbagbo, ma kalo

   K‘a jo yin Olorun wa,

   K‘a le d'ade ni ‘kehin.

Egbe: E yin logo...


3. A dupe lowo Olorun

   T'o fi Jesu Kristi fun wa

   Lati ra araiye pada,

   Lowo ese at’Esu.

Egbe: E yin logo...


4. Egbe Serafu damure

   Egbe Kerubu kun f 'adura

   Olugbala yio gba wa la

   Oluwosan yio wo wa san

Egbe: E yin logo...


5. Ojo mbo t‘aiye yio pin

   E sora enyin Mimo

   K'eni waju te siwaju

   K'eni ehin ma jafara.

Egbe: E yin logo...


6. Awon to segun saju

  Nwon nwo wa b’a ti nyo loni,

  Nwon nkan sara si wa wipe

  Te siwaju, ma fa s'ehin.

Egbe: E yin logo...


7. Ma siyemeji lona yi,

   B'o ti wu k'o le fun o to;

   Serafu mase foiya

   Adun y‘o kehin aiye re.

Egbe: E yin logo...


8. Nigbati ‘pe kehin ba dun

   Jesu y‘o ko wa de Kenaani,

   Je ka l'ayo lodo Re

   Fi wa s'agbala itura.

Egbe: E yin logo...


9. E f'ogo fun Baba Ioke

   E f'ogo fun Omo pelu

   E f'ogo fun Emi Mimo

   Metalokan lope ye fun.

Egbe: E yin logo... Amin

English »

Update Hymn