HYMN 97

(FE 114)1. OLORUN Eleda t’o d'egbe Seraf,

   Ati Kerubu s'orile ede aiye

   Lat‘owo Jesu Olugbala owon

   Awa nyin oruko Re logo.

Egbe: A! e ku ayo, eku ayo
 
      egbe Serafu

      A! e ku ayo, e ku ayo

      egbe Kerubu.


2. Nibo l'awon ayanfe Olorun wa?

   E wa gbo ohun Oluso-agutan yi

   E ronu piwada, e wa w'oko na;

   Igbala na ku si atel'owo.

Egbe: A! e ku ayo...


3. Egbe Kerubu, dupe lowo Olorun

   Tesiwaju ninu ogun emi jija

   E fere gbo ‘hun Oluwa wa Jesu,

   Wipe, o seun, omo rere.

Egbe: A! e ku ayo...


4. Enyin ti nkoja lo ya sodo Jesu

   Lati gb‘ore-ofe n‘nu egbe yi,

   Mase kegan oko igbala ‘kehin

   T'Olorun Metalokan fun wa.

Egbe: A! e ku ayo...


5. Jesu Oluwa mbowa joba laiye
 
   Larin Egbe Kerubu ati Serafu

   Egberun Odun ni ‘joba re ninu

   Egbe Mimo at'oke wa yi.

Egbe: A! e ku ayo...


6. Jesu Kristi Oluwa Oba Ogo

   L'opa iye ainipekun wa lowo re

   Yio ko gbogbo awon t’o gbagbo Io,

   Siwaju ite baba l'oke.

Egbe: A! e ku ayo... Amin

English »

Update Hymn