HYMN 98

(FE 115)
‘Ibukun Ii Oruko Oluwa lati isisiyi
lo ati si i lailai" - Ps. 113:21. ENYIN egbe Serafu,

   Wa fi ayo nyin han,

   E jumo ko orin didun

   Fun se‘yanu to se fun wa

   Ti ko je ka sonu kuro ni ona Re.

Egbe: A nyan lo si Sion,

      Sion to dara julo

      A nyan goke lo si Sion

      Ilu Olorun wa.


2. Baba Aladura

   F'ope fun Olorun

   To mu O bori awon ota

   Ti ko je ki ota yo o

   To fi o se ori

   Yio fi o se d’opin.

Egbe: A nyan lo...


3. Enyin Egbe Akorin

   E fi ayo nyin han

   Fun Majemu Re ti ko ye,

   Ni arin Egbe Serafu

   To mu se di oni,

   Ati aiye ti mbo.

Egbe: A nyan lo...


4. Enia Ie ma kegan

   Nwon si le ma sata

   Awon ti ko m'Olorun wa,

   Sugbon awa Egbe Kerubu

   A si m'eni t‘a nsin

   Yio si fun wa lere.

Egbe: A nyan lo...


5. Kerubu Serafu

   E mura sis'Emi

   Enyin yio sise na dopin

   E o si ri Olugbala

   L‘aye mimo loke

   Ati I’orun pelu.

Egbe: A nyan lo... Amin

English »

Update Hymn